Воспроизведено
-
Koko Ise wa toni ni:
EYA GBOLOHUN EDE YORUBA NIPA IHUN
(1) Gbolohun Eleyo Oro Ise: Eyi kii ni ju oro ise kan pere.
(2) Gbolohun Olopo-Ise: Irufe gbolohun yi maa n ni ju oro ise kan lo.
(3) Gbolohun Alakanpo: Eyi ni gbolohun meji tabi ju bee lo ti a papo se eyo kan nipa lilo oro asopo.
-
Eto Igbeyawo Abinibi ni Ile Yoruba
-
AROKO ASAPEJUWE.
-
Koko Ise: Ise oro Ise ninu gbolohun
Oro Ise ni emi gbolohun. Ohun kan naa ni opomulero to n toka isele inu gbolohun. Bi apeere:
-Dupe 'pon' omi.
Sade 'ra' bata.
Olu n 'ro' amala ni ori ina.
Ti a ba yo oro ise: pon, ra, ro kuro ninu awon gbolohun oke wonyi, ko lee ni itumo.
Ise Oro Ise:Oro Ise ni o maa n toka isele inu gbolohun. Eyi ni ohun ti oluwa se. Awon oro naa la fi sinu awon nisale yii.
- Sola (pon) omi.
- Dare (ko) ile.
- Jide (ge) igi.
- Iyabo (ka) iwe.
-Funmi (be) isu.
Ati bee bee lo.
Oro Ise le sise gege bi odindi gbolohun ki o si gbe oye oro wa jade
Bi apeere :
Jade.
Jeun.
Sun.
Sare. Ati bee bee lo.
A le lo oro ise lati pase iyisodi fun eniyan nipa lilo "ma" saaju ninu ihun gbolohun
Bi apeere "
Ma sun.
Ma sare. Ati bee bee lo.
A n fi oro ise se ibeere nipa lilo wunre asebeere: da, nko ati bee bee lo.
Bi apeere:
Titi da?
Tope nko?